Southern Illinois University Edwardsville Logo
Apply to SIUE


College of Arts and Sciences
CAS Masthead
 

Ìkíni Káàbọ ti Díìnì

Inú mi dùn láti kíi yín káàbọ sí Kọlẹjì Àsà àti Sáyẹnsnì ní Ilé Ìwé Gíga ti Southern Illinois ní Edwardsville. Kọlẹjì náà tí a mọ sí CAS ni ó n pèsè kíláàsì fún gbogbo akẹkọọ nínú yunifásítì gẹgẹ bí ara ìlànà ẹkọ gbogbogbò rẹ àti àwọn ẹkọ pàtó ní àsà, ẹkọ ọmọnìyàn, ẹkọ ìmọ sáyẹnsì, àti sáyẹnsì ará ìlú. Láti ètò kíkọ nípa átọmù àti irúfẹ ẹmí tó kéré jùlọ títí dé àwọn oun tó n darí ọrọ ajé àti ètò ìsèjọba ní àwọ agbegbè wa, CAS n pèsè ju iwé ẹrí 50 fún odún mẹrin àkọkọ àti ìmọ ìjìnlẹ míràn láti èyí tí a pilẹ se títí dé ẹlẹkajẹka.

Gbogbo eléyìí ló seése nípa ẹka isẹ àti ètò wa tí o fẹẹ tó 30 nínú Kọlẹjì tó n pèsè ìlànà ẹkọ náà nípasẹ ó fẹẹ tó àwọn olùkọ 350 tí wọn nkọ ó fẹẹ tó akẹkọọ 8,000 lọdọọdún. O ju akẹkọọ 850 lọdọọdún tí wọn n gba iwé ẹrí wọn nípasẹ Kọlẹẹjì náà. Sùgbọn nọmbà nìkan kò le sọ gbogbo rẹ tán.

Oun tí ó mú CAS se pàtàkì ni bí wọn se n pèsè ètò ẹkọ fún àwọn olùkọ wọn. Wọn tẹpá mọ bí wọn yóò se sin àwọn akẹkọọ wa, wọn sì n tẹpá mọ kíkọ láàrín gbèdéke ètò ẹkọ tó ga jù láti ríi dájú wípé a lè dásí oun èlò gbogbo ìlú ní àpapọ, bóyá ní ìsìnyí tàbí ní ọjọ ìwájú. Eléyìí ni a n se nípa pípín ìmọ yíká, mímúdàgbà bí wọn se n ronú jinle, àti fífún wọn ní oun èlò ọgbọn láti mú wọn jẹ ará ìlú tó wúlò nínú agbegbè wa yìí tó n yípo lójoojúmọ. Ìran wa ni ó hàn nínú ọrọ wa nípa Irúfẹ Ìhùwàsí àti Agbara àwọn Akẹkọọjáde wa.

Jọwọ lo àsìkò díẹ yìí láti wo àwọn ànfàní mèremère tí ó wà lárọwọtó rẹ àti láti wo gbogbo oun rírì tí awọn tó n kẹkọọ ní Kọlẹjì yìí ti se. Púpọ nínú àwọn oun rírì tí a ti se ni o lè rí nínú ẹka Ìròyìn (News) àti Àkọsílẹ (Notes) níbí yìí. Tẹ lóríi àkójọ ìwé ẹrí àti àwọn ètò láti wo awọn oun pàtó tí a n pèsè, tàbí kí o kàn sí ojú ìwé ayélujára (website) èka ẹkọ kọọkan fún àlàyé lẹkùnrẹrẹ.

Kàn sí wa nípa ímeèlì tàbí kí o pè wá ní (618) 650-5044. Bí ó bá wù ọ láti darapọ mọ wa gẹgẹ bíi akẹkọọ tó sẹ n wọlé, gẹgẹ bíi akẹkọọ tuntun tàbí akẹkọọ tó wá láti ibòmíràn, o lè kàn sí ọfísì wa ní ọfísì ìgbaniwọlé SIUE (admissions) ní 1-800-447-SIUE.

Díìnì

 
facebookoff twitteroff vineoff linkedinoff flickeroff instagramoff socialoff